Àwọn iṣẹ́

Safe2choose ń dàgbà bẹ́ẹ̀ni ó sì ń gbèrú síi, nítorínà a nílò àwọn ènìyàn tí ó ní ìrírí tí ó sì fakọyọ láti le ṣe àṣeyọrí lórí àwọn ète wa – láti tọ́ka àwọn obìnrin ní àgbáyé sí ìmọ̀ tí ó péyẹ tí ó sì yẹ fún ẹni kọ̀ọ̀kan lórí ìsẹ́yún tí kò léwu, kí wọ́n le sẹ́yún láìléwu ní ibi, ìgbà àti pẹ̀lú ẹni tí ó tẹ́ wọn lọ́rùn jùlọ.

Ìpinnu wa:

À ń pèsè ìmọ̀ tí ó dá lórí ẹ̀rí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní lórí ìsẹ́yún tí kò léwu.
À ń dáni ní ìmọ̀ràn tí kò léwu, tí kò hàn sáráyé, tí ó rọrùn tí kò sì ní ìdájọ́ tàbí ìtìjú.
A má ń gbìyànjú láti rán ọ lọ sí àwọn ilé – isẹ́ tí ó sé fọkàn tán tí o bá nílò rẹ̀.
Ó rọrùn láti bá wa pàdé, a dùn bá sọ̀rẹ́, a sì sé bá rìn
A bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ rẹ láti yan ipa tí o fẹ́ lórí ilé àti ayé rẹ.

Wá àwọn iṣẹ́ tí ó wà nílẹ̀ níbí:

Kò sí ǹkan fún ọ?

À ń fi ààyè gba ìwé ìwásẹ́, bóyá láti ṣiṣẹ́ gbowó tàbí iṣẹ́ ọ̀fẹ́.
Tẹ àtẹ̀ ránsẹ́ sí wa ní recruitment@safe2choose.org