Ṣé ò ń wá àlàyé nípa àti ìlànà oyún ṣíṣẹ́ tí kò béwu dé ní safe2choose? Àwọn ìrírí àwọn èèyàn, òfin tí ó wà fún ìlú kọ̀ọ̀kan, àwọn búlọ́ọ̀gì àti àwọn ohun ìrànwọ́ mìíràn lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yan ìlànà rẹ.
Àlàyé nípa oyún ṣíṣẹ́ ní orílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kan
Àǹfààní láti ṣẹ́ oyún àti láti gba ìtọ́jú yàtọ̀ gédégbé láti orílẹ̀ èdè kan sí ìkejì. Láti mọ ohun tí ààyè gbà ní orílẹ̀ èdè rẹ, wo abala àwọn orílẹ̀ èdè.
Àwọn ohun ìrànwọ́
A fẹ́ kí ó rọrùn fún ọ láti rí àlàyé nípa oyún ṣíṣẹ́. A ti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ìlànà oyún ṣíṣẹ́ tí o lè gbà lórí ẹ̀rọ ayélujára (pdf), àwọn fídíò atọ́nisọ́nà, àti àbájáde ìwádìí wa sí orí àpèrè yìí.
Ìrírí níbi oyún ṣíṣẹ́
Oyún ṣíṣẹ́ jẹ́ ìrírí tí ó wọ́pọ̀ láàrín àwọn obìnrin. Sísọ ìtàn rẹ le jẹ́ irinṣẹ́ tí ó lágbára láti jẹ́ kí ìtọ́jú oyún ṣíṣẹ́ jẹ́ gbígbà, ó sì tún le ran àwọn obìnrin lọ́wọ́ láti ní ìgboyà láti ṣe èyí tí o ṣe. Kà (tàbí sọ) ìtàn oyún ṣíṣẹ́ àwọn obìnrin láti orílẹ̀-èdè rẹ.