ìṣẹ́yún pẹ̀lú ògùn

Iṣẹyun pẹlu Awọn oogun

Ìṣẹ́yún oníṣègùn [1] ni a mọ̀ sí ìṣẹ́yún pẹ̀lú ògùn. Àwọn mìíràn á ma pe ọ̀nà yí ní ìṣẹ́yún ara ẹni, ìṣẹ́yún ìṣàkóso fúnra eni [2] tàbí ìṣẹ́yún ṣeé fúnra rẹ (DIY)

Tí o bá lo ògùn ìṣẹ́yún o ó rìí ìrírí ẹ̀jẹ̀ dídà àti inú rírun. Àwọn àmì àìsàn náà jọ ti nǹkan oṣù rẹ tàbí bí ẹni pé oyún rẹ ń bàjẹ́ (ìṣẹ́yún aláìfọwọ́fà)

Àwọn ògùn ìṣẹ́yún ní gbogbo ìgbà túmọ sí lílo mifepristone àti misoprostol ní ṣíṣe n tẹ́lẹ tàbí lílo misoprostol nìkan

Mifepristone

– Mifepristone jẹ́ ògùn tí ó má n pagidínà sísan progesteron, èyí tí ó je hòmónùù tí ó má ń ṣe àtìlẹyìn fún oyún. Láì sí progesteron, oyún náà kò le dàgbà. Mifepristone jẹ́ Ìdàjì kan nínú ohun tí gbogbo wa mọ sí ògùn ìṣẹ́yún tabi ìṣẹ́yún oníṣègùn, òhun fúnra rẹ kò lè dá nìkan ṣé oyún [3]

– Mifepristone tún má ń jẹ́ kí ẹnu ònà ilé omo rọ (ìsàlẹ ilé ọmọ) èyí ni yíò jẹ́kí misoprostol ṣiṣẹ́ kíkan kíkan. [4]

– Mifepristone nìkan kò tó láti ṣẹ́yún, a nílò Misoprostol náà [5]

– Ní pàtàkì a máá ń lo Mifepristone fún ìṣẹ́yún tàbí oyún bíbàjẹ́, nítorínà lórí àwọn ètò àti àwọn ìhámó ní orílẹ-èdè kọ̀ọ̀kan, ìgbàmíràn a máa ṣòro rí [6]

Misoprostol

– Misoprostol jẹ́ ògùn tí ó máá ń mú kí ilé ọmọ sùn (tàbí kí ó fun pọ) èyí sì ma jẹ́kí oyún wálẹ pẹlú inú rírun àti ẹjẹ dídà

– A lè ṣẹ́ ìṣẹ́yún oníṣègùn pelu Misoprostol láì lo mifepristone, àmọ́ lílo méjèèjì papọ má ń múnádóko

– Misoprostol ní àwọn ìwúlò ètò ìlera mìíràn fún ìṣẹ́yún yàtọ̀ sí ìṣẹ́yún (fún ìrọbí, ìsun ẹjẹ lẹ́yìn ọmọ bíbí, ọgbẹ́ inú àti bẹ́ẹ bẹ́ẹ lọ) nítorí náà ó ṣeé ri ni arọwọ́tọ́. [7]

Àjọ Ètò ìlera àgbáyé ka mifepristone àti Misoprostol sí oyún gbòógì àti wípé wọ́n wà fún ìṣẹ́yún tí kò léwu [8]

Láti mọ bí a ṣe lè ṣẹ́yún tí kò léwu tó sì munadoko pèlú mifepristone àti Misoprostol tẹ ibí. Bí o bá ń lo Misoprostol nìkan tẹ ibí

Àìléwu ògùn ìṣẹ́yún àti àwọn ìgbà tí kò tọ́:

ìṣẹ́yún oníṣègùn kò léwu fún ọpọlọpọ obìnrin. Àwọn ipò bí mélòó kan ló wà tí ògùn ìṣẹ́yún kò tọ́ fún [9]

A gbà ó níyànjú láti lọ mifepristone tí:

– O bá tí ń lọ àwọn sítẹ́ríọdù (bí prednisone tàbí dexamethasone). Àmọ́ o lè ṣẹ́yún pẹlú misoprostol nìkan

A gbà ó níyànjú láti lo mifepristone àti misoprostol bí [10]:

– O bá ń lo àwọn alákọjá(a mú ẹjẹ sàn) bíi heparin àti warfarin

– O bá ní ìṣòro ẹjẹ bíi Porphyria

– Ọjẹ rẹ bá kùnà pátápátá láti ṣiṣẹ́

– O ní ìrira fún mifepristone, misoprostol tàbí prostaglandons. Ọnà kan ṣoṣo láti mọ bóyá ó ní ìrira ni tí ó bá ti lòó tẹ́lẹ rí tí ó sì ní ìnira. Kò ṣẹ́ẹ́se láti mọ bí ó bá ma ní ìrira tàbí o kò ní ní láì tí lo ògùn náà

– O ní oyún ectopic (ní ìta ilé ọmọ). Ní ọràn yí, ògùn ìṣẹ́yún kò ní ṣé, o lè ṣe àmọ́ kò ní ṣé oyún náà. Tí o bá mọ pé o ní oyún ectopic o níláti wá ìtójú oníṣègùn

Tí ó bá ní IUD(ẹrọ nínú ilé omo) kò kí ń ṣe ìdènà fún ìlò ògùn ìṣẹ́yún, àmọ́ o nílò ìsọ́ra díè. Ewu àti ní oyún ectopic (oyún ìta ilé ọmọ) a máa pò si bí ìwọ bá ní IUD lára. Inú rírun náà a sì máa lágbára tí ó bá lọ ògùn náà nígbà tí IUD wà lára rẹ Inú rírun náà a sì máa lágbára tí ó bá lọ ògùn náà nígbà tí IUD wà lára rẹ
Tí ó bá ṣeé ṣe ìmọràn tí ó dára jù ni kí o yo IUD kí o tó lo ògùn ìṣẹ́yún [11]

Tí o kò bá mọ bí ògùn ìṣẹ́yún yìí dára fún ọ kàn sí wa! A lè bá ẹ wò ó bí ona yí dára fún ọ

Rántí wípé iṣẹ́ safe2choose nìkan ni láti rán àwọn obìnrin tí yóò lo ògùn ìṣẹ́yún ni ọsẹ mókànlá àkókò ti ìlóyún. Tí oyún rẹ bá ju bẹ́ẹ lọ, a ó ṣe akitiyan láti tọ́ka àjọ mìíràn tí ó lè ràn ó lọ́wọ́ [12]

contraindications to the abortion pills

Ohun tí o ní láti retí nígbà tí o bá fi ògùn ṣẹ́yún

lẹ́yìn tí ó bá lo ògùn ìṣẹ́yún náà o máa rí àwọn àmì àìsàn tó fara jọ nǹkan oṣù tàbí oyún tó wálẹ tí ó bá ń lọ mifepristone, ògùn yìí kì í sábà fa àmì àìsàn kankan. Ọpọlọpọ àmì àìsàn yìí yíò ṣẹṣẹ farahàn lẹ́yìn ìgbà tí ó bá lo misoprostol

Àwọn àmì àìsàn náà ni: inú rírun ẹjẹ dídà,wákàtí méjìdínláàdọta àkókò tí ó lo misoprostol, àmì ẹjẹ dídà le máa wáyé kó sì máa lọ fún ọjọ púpò tàbí ọṣẹ púpò [13]

Misoprostol le fa àwọn àbájáde kòbàkúńgbè fún ìgbà péréte bíi ibà, ìgbé gbuuru, èébì àti orí fífó. Tí o kò bá ní ìrírí àwọn nǹkan wọnyí, ó ṣe déédéé dáradára. Tí o bá sì ní, won ó pòórá láàrín wákàtí méjìdínláàdọta tàbí kí ó má tó bẹ́ẹ [13]

Kàn sí wa kí a lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tí èyí bá jẹ́ ọràn tìrẹ

Àti mọ bí ògùn ìṣẹ́yún bá ṣiṣẹ́

Tí ó bá lo ògùn náà ní ìbámu pèlú àwọn ètò tí a fi gbà ó ní ìmòràn, tí ẹjẹ rẹ si dà tó nǹkan oṣù rẹ (tàbí ju bẹ́ẹ lo) fun òpòlopò ìgbà kí ìṣẹ́yún oníṣègùn náà ti jẹ́ àṣeyọrí. Ó yẹ kí àwọn atọ́ka oyún rẹ (ọmú tútù, èébì, rírè) máa pàwòdà díẹdíè kí wón sì pòórá láàárín ọjọ́ márùn-ún tí o lo ògùn ìṣẹ́yún. Èyí jẹ́ ìtọ́kasi dídára mìíràn wípé àwọn ògùn náà ṣe iṣẹ́ àṣeyọrí [11]

Bi kò tilẹ pa dandan, tí ó bá wù ọ́ láti rí ìdánilójú tí ó dunjú o lè mú òkan lára àwọn àyèwò wọnyí :

Àyẹ̀wò ìtọ̀(hcg ìtò) : Èyí jẹ́ àyèwò tó rọrùn jù lọ tí a lè ṣe fún ìdánilójú, nítorí pé ó ṣeéṣe ní ìkọ̀kọ̀ ilé rẹ. A gbà ọ́ níyànjú wípé kóo dúró fún bíi ọsẹ mẹ́rin lẹ́yìn ìgbà tí ó lo ògùn ìṣẹ́yún. Tí ètò náà bá jẹ́ àṣeyọrí, ó yẹ kí àyèwò náà jé òdì lẹ́yìn ọsẹ bii mẹ́rin

Àyẹ̀wò ẹjẹ (hcg iye) : àyẹ̀wò yìí nílò ìbẹ̀wò oníṣègùn, a sì máa wúlò gidi tí ó bá jẹ́ àyèwò ẹjẹ kan náà ni o ṣe kí o tó lo ògùn ìṣẹ́yún láti le fi àwọn ìpele hòmónùù náà wé ra. A kìí ṣe àyẹ̀wò yíì nígbà gbogbo nítorí náà tí ó bá wù ọ́ láti rí ìdánilójú, wón á máa gbani níyànjú àyẹ̀wò yìí, hòmónùù oyún náà yíò tí kúrò láàárín ọsẹ mẹ́rin lẹ́yìn ìgbà tí o lo ògùn yìí tí ètò náà bá jẹ́ àṣeyọrí

Àyẹ̀wò ilé ọmọ: Èyí nílò ìbèwò oníṣègùn àti wípé ó lè rí oyún tó sì wà nínú. Níi lọ́kàn wípé tí ògùn ìṣẹ́yún náà bá ṣiṣẹ́, àwọn ẹ̀jẹ̀ àti àsopò díẹ̀díẹ̀ le sì hàn lórí àyẹ̀wò inú fún ó kéré tán ọ̀sẹ̀ méjì. Bí oyún náà bá tilè tí wálẹ̀, ìgbà mìíràn tí a bá tètè ṣe àyẹ̀wò ilé ọmọ àwọn onímọ̀ nípa ìlera le wípé àwọn obìnrin mìíràn ní ìṣẹ́yún tí kò parí èyí le jásí iṣẹ́ abẹ tí kò wúlò. Tí ó bá wù ọ́ láti ṣe àyẹ̀wò ilé ọmọ, a gbà ó níyànjú láti dúró fún ó kéré tan ọ̀sẹ̀ méjì, àyàfi tí o bá ní àmì ìnira tí o sì tètè nílò àyẹ̀wò ilé ọmọ

Tí wákàtí méjìdínláàdọta lẹ́yìn ìgbà tí o lo misoprostol tó gbèyìn bá kọjá tí ẹ̀jẹ̀ ko sì tíì dá tàbí èjè tó dà kò tó nǹkan oṣù rẹ, ó seése kí ìṣẹ́yún náà máà jẹ́ àṣeyọrí [14]

Ní ọpọlọpọ ìgbà, ó ṣeéṣe kí o tún lo ògùn ìṣẹ́yún. Kàn sí wa kí a lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tí èyí bá jẹ́ ọràn tìrẹ

Ìtọ́jú oníṣègùn lẹ́yìn ògùn ìṣẹ́yún

Tí àwọn àmì ìlera rẹ bá jẹ́ bó ti yẹ kó jẹ́ tí o ko sì rí àwọn àmì ìkìlọ kankan, o kò nílò ìtọ́jú oníṣègùn. Kò ṣe pàtàkì láti ṣe àyèwò oyún tabi ọ́tírásáǹdì lẹ́yìn náà, yálà ṣíṣe iṣẹ́ abẹ bí D & C

how to know if the abortion pills were effective

Àti bímọ àti nǹkan oṣù lẹ́yìn ìṣẹ́yún

Leyin ìṣẹ́yún (oníṣé abẹ tàbí oníṣègùn) nǹkan oṣù rẹ yíó tún bẹrẹ, bi ẹni pé o ti ń ṣe nǹkan osu tele. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá o ó sì yé ẹyin inú. Èyí túmò sí wípé o lè tún lóyún tí o bá ní ìbálòpọ láì ní ìdábòbò [11]

Tí o kò bá tíì ṣetán láti lóyún, o ní láti fiyè sí àwọn ona ìdènà oyún. O le ri àlàyé síi ni FindMyMethod.org

Nǹkan oṣù rẹ le padà láàárín ọsẹ mẹ́rin sí mẹ́fà lẹ́yìn ìgbà tí o lo ògùn ìṣẹ́yún [15]

Awon òǹkòwé:

Ńipasè ikọ safe2choose àti àwọn ọ̀mọ̀ràn ní carafem, ní ìbámu pẹ̀lú Ìmọ̀ràn ìgbìmò ìjọba àpapọ̀ lórí ètò ìsẹ́yún (NAF)

Àjọ gbogboògbò lọ́rí ìsẹ́yún jẹ́ ẹgbẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ abánisẹ́yún ní Àríwá Amẹ́ríkà.

carafem ń pèse ètò ìsẹ́yún àti ìfètò sọ́mọ bíbí tí ó rọrùn tí ó sì dájú kí àwọn ènìyàn le ṣàkóso iye àti àyè tí ó wà láàrin àwọn ọmọ wọn.

[1] World Health Organization. Safe abortion: technical and policy guidance for health systems. Retrieved from: https://apps.who.int/iris/bitstream/handle/10665/70914/;jsessionid=B7AEEBE4F34809D869F73B1ABA7F6221?sequence=1

[2] Reproductive Health Matters. Self-management of medical abortion: a qualitative evidence synthesis. Retrieved from: https://www.tandfonline.com/doi/pdf/10.1016/j.rhm.2016.06.008?needAccess=true

[3] Children by Choice. Medication abortion. Retrieved from: https://www.childrenbychoice.org.au/information-support/abortion/medication-abortion-2/

[4] S. Hopkins MD, M. Fleseriu MD. Chapter 7 – Medical Treatment of Cushing’s Disease. Retrieved from: https://www.sciencedirect.com/science/article/pii/B9780128043400000073

[5] Thoai D Ngo, Min Hae Park, Haleema Shakur & Caroline Free. Comparative effectiveness, safety and acceptability of medical abortion at home and in a clinic: a systematic review. Retrieved from: https://www.who.int/bulletin/volumes/89/5/10-084046/en/

[6] Brooke Ronald Johnson, Vinod Mishra, Antonella Francheska Lavelanet, Rajat Khosla & Bela Ganatra. A global database of abortion laws, policies, health standards and guidelinesArticle has an altmetric score of 221. Retrieved from: https://www.who.int/bulletin/volumes/95/7/17-197442/en/

[7] Webmd. Misoprostol. Retrieved from: https://www.webmd.com/drugs/2/drug-6111/misoprostol-oral/details

[8] WHO. Access to essential medicines as part of the right to health. Retrieved from: https://www.who.int/medicines/areas/human_rights/en/

[9] Ipas. Medical abortion contraindications and precautions. Retrieved from: https://www.ipas.org/clinical-updates/general/ma-precautions

[10] WHO. Essential Medicines List Application Mifepristone–Misoprostol for Medical Abortion. Retrieved from: https://www.who.int/selection_medicines/committees/expert/22/applications/s22.1_mifepristone-misoprostol.pdf?ua=1

[11] Ipas. (2019). Clinical Updates in Reproductive Health. L. Castleman & N. Kapp (Eds.). Chapel Hill, NC: Ipas. Retrieved from: https://www.ipas.org/wp-content/uploads/2023/09/Ipas-Clinical-Updates-in-Reproductive-Health-CURHE23b.pdf

[12] National Abortion Federation. 2020 Clinical Policy Guidelines for Abortion Care. Retrieved from: https://5aa1b2xfmfh2e2mk03kk8rsx-wpengine.netdna-ssl.com/wp-content/uploads/2020_cpgs_final.pdf

[13] Planned Parenthood. How does the abortion pill work? Retrieved from: https://www.plannedparenthood.org/learn/abortion/the-abortion-pill/how-does-the-abortion-pill-work

[14] Gynuity. Abortion with self-administered misoprostol. Retrieved from: https://gynuity.org/assets/resources/polbrf_misoprostol_selfguide_en.pdf

[15] BPAS. Caring for yourself after your abortion. Retrieved from: https://www.bpas.org/abortion-care/abortion-aftercare

Oyún ṣíṣẹ́ tí kò béwu dé pẹ̀lú òògùn

Our services