Ìtósónà fún ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọ̀wọọ́yí (MVA)

Protocol ng Vacuum Aspiration

Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọ̀wọọ́yí (MVA) tàbi ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ iná (EVA) jẹ́ ọ̀nà ìsẹ́yún onísé abẹ tí a fi ń ṣẹ́yún tí ó ti tó ọ̀sẹ̀ kẹrìnlá (MVA) àti ọ̀sẹ̀ kẹ́ẹ̀dógún (EVA). Ojú ewé yìí sàlàyé nípa àwọn ìlànà ìṣẹ́yún wọ̀nyí.

Kí ni ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọ̀wọọ́yí (MVA)?

Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọ̀wọọ́yí (MVA) jẹ́ ọ̀nà aláìléwu tí a fi ń ṣẹ́yún tí ó bá wà ní oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́, àti /tàbí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù mẹ́ta èkejì títí yóò fi dé ọ̀sẹ̀ kẹrìnlá.[1] Ilé ìwòsàn pẹ̀lú alábòójútó ìlera pípé tí ó ń ṣe ètò náà ni yóò sọ ìgbà tí oyún ti kọjá èyítí MVA le ṣe.

Alábòójútó tí ó kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ ni ó má ń ṣe MVA ní ilé ìwòsàn.

Nígbàtí ètò náà bá ń lọ, oníṣègùn yóò lo àwọn irinṣẹ́ bíi ẹ̀rọ afaǹkan tí kìí pariwo láti fi yọ oyún náà láti ilé ọmọ. [2] Lọ́pọ̀ ìgbà a má ń ṣe ètò yìí nípa lílo ògùn ìbílẹ̀ tí kìí jẹ́ ká fura, èyí má ń lo ìṣẹ́jú márùn-ún sí mẹ́wàá. Ó ṣeé ṣe kí obìnrin náà ó rí ìrírí inú rírun nígbàtí a bá ń ṣe ètò yìí, ó sì lè máa sun ẹ̀jẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ lẹ́yìn náà. O lè rí àlàyé síi níbí.

MVA jẹ́ ẹ̀rọ aláfọ̀wọọ́yí ṣùgbọ́n a sì lè mọ̀ọ́ sí ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ, ìṣẹ́yún onípinnu, ìṣẹ́yún àfàmọ́ra tàbí ẹ̀rọ ìṣẹ́yún. [1]

Kí ni ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ iná (EVA)?

Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ iná jẹ́ ọ̀nà aláìléwu (EVA) ó sì fẹ́ fara pẹ́ ọ̀nà Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (MVA). A lè lo EVA fún oyún tó wà ní oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́, àti /tàbí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù mẹ́ta èkejì. Alábòójútó akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni ó má ń ṣe EVA ní ilé ìwòsàn.

Nígbàtí ètò náà bá ń lo, oníṣègùn yóò lo àwọn irinṣẹ́ bíi ẹ̀rọ afaǹkan oníná fi yọ oyún náà láti ilé ọmọ.

Ìyàtọ̀ àkọ́kọ́ láàárín EVA àti MVA ni pé iná ni à ń lò láti fi ṣe irinṣẹ́ tí a ó fi yọ oyún. Nítorípé EVA nílò iná, ó le má wà níbi tí àwọn ohun àmúlò kò tíì wọ́pọ̀. Níbi tí ó bá wà, àwọn oníṣègùn le lo ọ̀nà EVA bí oyún ṣe ń lé síi lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá sí méjìlá nítorí ó gba àwọn oníṣègùn láàyè láti ṣe ètò yìí kíákíá ju ti MVA lọ. Nípa bẹ́ẹ̀ yóò dín àkókò tí ètò náà yóò gbà fún obìnrin náà kù. Ìyàtọ̀ ńlá míràn ni pé EVA ní ṣe pẹ̀lú ariwo nítorí ó ń lo iná. [2]

Kí ni óń ṣẹlẹ̀ nínú ètò ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọ̀wọọ́yí (MVA)

1. Òògùn lílò ṣáájú ètò

Àjọ ìlera àgbáyé (WHO)gbà á ní ìyànjú pé kí wọ́n máa lọ egbòògì kí wọ́n tó ṣe ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọ̀wọọ́yí (MVA). Èyí yóò dín ewu àkóràn kù. [1]

Síbẹ̀ síbẹ̀, bí kò bá sí egbòògì a sì le ṣé oyún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọ̀wọọ́yí láì léwu. Bí ó bá wu ilé ìwòsàn wọ́n lè fún ọ ní òògùn ọ̀rọ̀ ẹnu tí yóò ṣe ìrànwọ́ fún ìrora inú rírun bíi ibuprofen. [2]

2/ Ní ìgbàradì fú ìsẹ́yuń pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (MVA)

tests-before-a-vacuum-aspiration

Nígbà tí o bà ṣe ìbẹ̀wò sí ilè ìwòsaǹ fún ìsẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (MVA) tabi ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ iná (EVA), àwọn ìgbésẹ̀ tí ìwọ yóò gbé fún ìgbàradì ètò náà nì wọ̀nyí (ṣùgbọ́n kò lópin fún) [2]:

  1. Ìgbéyẹ̀wò ìtọ̀ olóyún
  2. Wíwo irú ẹ̀jẹ̀ tí ó ní
  3. Ọ́lútírásáǹdì láti le ṣírò iye oṣù tí ọmọ wà
  4. Ìdánwò lórí eegun ìkòkò ìdí

Wíwon èéfún ẹ̀jẹ́

A lè ṣe àwọn ìdánwò díè síi bí o bá nílò rẹ̀, a sì máń wo àwọn òfin tó so móo ní ibikíbi tí o bá wà.

3/ Nígbà tí o bá ń ṣe ìsẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí

Ìgbésẹ̀ Kiní. Ètò ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (MVA) tàbí ti oníná (EVA) yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìdánwò lórí eegun ìkòkò ìdí tàbí fífè ẹnu

Ìgbésẹ̀ Kejì. Àó gún òògùn ìbílè tí kìí jẹ́ ká fura pẹ̀lú a bẹ̀rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ.

Ìgbésẹ̀ Kẹta. Oníṣègùn yóò wà bẹ̀rẹ̀ sí í la ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ díèdíè, iye ọ̀sẹ̀ tí oyún bá wà ní yóò sọ bí ètò yìí yóò ṣe lọ.

Ìgbésẹ̀ Kẹ́rin. Lógán tí a bá ti yege nínú ètò náà, oníṣègùn yóò lo ẹ̀rọ tí a fíń fa nǹkan nínú tí kìí pariwo tí àń pè ní lpas fi sẹ́yún yóò sì yọ oyún náà.

Ìgbésẹ̀ Karùn-ún. Lẹ́yìn tí a bá ti yọ oyún, ẹni tí ó ń ṣeé le yàn láti ṣe Ọ́lútírásáǹdì, lẹ́yìn náà obìnrin náà le sinmi. [2]

steps vacuum aspiration abortion

4/ Lẹ́yìn ìsẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (MVA)

Ara yíyá làti àìlera Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọyí (MVA) tàbí ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ iná (EVA) kò pẹ́ rárá.

  • Fún àwọn obìnrin tí ó ṣe ètò òògùn ìbílẹ̀ tí kìí jẹ́ ká fura, àsìkò ìmúláradá wọn kò tó ọgbọ̀n ìsẹ́jú
  • Fún àwọn obìnrin tí a fún ní òògùn ìfọ̀kànbalẹ̀ fún ètò náà, àsìkò ìmúláradá le pẹ́ díẹ̀ (ọgbọ̀n ìsẹ́jú sí ọgọ́ta ìsẹ́jú) títí tí ipa òògùn náà yóò fi lọ sílẹ̀.

Lọ́gán tí àsìkò ìmúláradá ní ilé ìwòsàn bá ti pé, obìnrin náà yóò lọ sílé rẹ̀. Àwọn ilé ìwòsaǹ mìíràn le bèrè fún ikò fún ìdábòbò rẹ̀ tàbí ẹnìkan tí yóò múu lọ sílé, ṣùgbọ́n èyí dálé ilé ìwòsàn tí ó jé. [2]

5/ Ìtọ́jú lẹ́yìn tí o ti sẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (MVA)

Lẹ́yìn ìsẹ́yún iṣẹ́ abẹ láì léwu, a máń gba obìnrin níyànjú láti máa bẹ ilé ìwòsàn wò lóòrèóòrè, bí kò bá sì le se èyí, kí obìnrin kọ̀ọ̀kan kí ó tèlé ìmọ̀ràn alábòójútó ìlera rẹ̀.

Kò sí iye àkókò kan pàtó tí obìnrin ní láti fi dúró tí yóò fi máa ṣe àwọn ìṣe pàtó bíi: ìwẹ̀ wíwẹ̀, ère ìdárayá, ìbálòpọ̀ tàbí wíwo àwòtẹ́lẹ́ nǹkan oṣù tí ó má ń wọ ojú ara. Lápapò, a gbáà ní ìmọ̀ràn pé títí tí ẹ̀jẹ̀ náà yóò fi dá lẹ́yìn oyún ṣíṣẹ́ náà, kí obìnrin náà ṣọ́ra láti máa ki àwọn nǹkan bíi àwòtẹ́lẹ́ nǹkan oṣù tí ó má ń wọ ojú ara lọ, agolo nǹkan oṣù tí má ń wọ ojú ara lọ, kí wọ́n sí ṣọ́ra fún iṣẹ́ alágbára. Obìnrin kọ̀ọ̀kan le padà sí iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ tí agbára rẹ̀ bá gbẹ, obìnrin a sì máa yàtọ̀ síra.

Kí o tó kúrò ní ilé ìwòsàn, ó yẹ kí á ṣàlàyé nípa ọ̀nà tí o kò fi ní lóyún. Àwọn ọ̀nà tí o lè gbà tí o kò fi ní lóyún le bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ síbésíbẹ̀, ìjíròrò yẹ kó wáyé nípa obìnrin kọ̀ọ̀kan àti ọ̀nà tí ó yàn. Ó yẹ kí ilé ìwòsàn ó pèsè ibi tí wọn yóò ma pè sí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wọn ní ìbéèrè tàbí ìfiyèsí lẹ́yìn oyún ṣíṣẹ́. [2]

Láti wá ọ̀nà tí kò fi ní lóyún tó bójúmu tí ó sì wù ọ́ kàn sí www.findmymethod.org

irinsẹ́ MVA tí à ń lò nínú ètò náà

Ìsẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (MVA) níse pẹ̀lú lílo irinsẹ́ kan tí àń pè ní Ipas. Ipas yìí jẹ́ ẹ̀rọ afaǹkan tí kìí pariwo tí a fíń yọ oyún. [2] O lè rí àlàyé síi lórí ẹ̀rọ Ipas níbí

Ipas equipment manual vacuum aspiration abortion mva

Ẹ̀rọ ìṣẹ́yún tó jẹ́ ti oni’ná (EVA) ti a má ń lò fi ṣẹ́yún

ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ iná (EVA) maá ń lo ẹ̀rọ olùfà eléyìí to so papọ̀ mọ́ túúbù ti dọ́kítà máa n tìbọ inu láti fọn atẹ́gùn sí oyún. Ẹ̀rọ ìṣẹ́yún oníná máa ń dún bi eṣinṣin ni àkokò yìí.

Àwọn àbájáde tí ó wọ́pọ̀ lẹ́yìn Ìṣẹyún pẹ̀lú Ẹrọ aláfọwọ́yí

Eléyìí tó wọ́ pọ̀ jù nínú ìrora to jẹ mọ́ ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí ni inú rírun ti obìrin má ti wọn bá ń ṣe é lọ́wọ́. Inú rírun yìí le lọ’lẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá parí, ṣùgbọ́n àwọn obìrin mí le ma ṣe inú rírun tó n lọ, tó ń bọ̀ for bi ọjọ́ díẹ̀ tàbi ọ̀ṣẹ̀ díẹ̀. A le gbógun ti eléyìí pẹ̀lú àwọn ògùn NSAID bíu ibuprofen.

Àwọn ògùn orun tó jẹ́ ti ìbílẹ̀ le è jẹ́ lílò ti wọn ba n ṣe ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí , eléyìí má jẹ́ kí wọn má le mọ ìnìra nibi ìkùn wọn ti wọn bá ń ṣe ìṣẹ́yún náà. [1]

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin yóò ní ìrírí ìsun ẹ̀jẹ̀ àti inú rírun nígbà tí a bá ń ṣe ìṣẹ́yún iṣẹ́ abẹ àti lẹ́yìn ìgbà tí a bá ṣeé tán.

Ó tún wọ́pọ̀ pe kí wọ́n ní oríṣiríṣi ìrírí lẹ́yìn ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ, gbogbo èyí kò jẹ́ tuntun, bí obìnrin náà bá sì rò pé òún nílò ìrànlọ̀wọ́ síi, kí ó béèrè fún ìrànlọ̀wọ́ olùbánidámọ̀ràn. [1]

Àwọn ewu àti ìnira tí ó má n wá nípa ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí

Bí ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí ṣe jẹ́ aláìléwu tó, àwọn ewu díẹ̀ sọ mọ́ ètò náà bíi: ìsun ẹ̀jẹ̀, àkóràn, ìpalára fún ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ àti àwọn ẹ̀yà tó wà láyìíká rẹ̀, oyún tí kò ṣe tán, oyún tó ń dàgbà síi.

Àwọn ewu yìí kò ní pò tó bá jẹ́ pé akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn ló ṣeé, ṣùgbọ́n ó se pàtàkì fún ọ láti mọ̀ nígbàtí o bá gbà láti ṣe ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ.

Ètò ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí tí kò bá mú ewu lọ́wọ́ kìí fa àìlebímọ ọjọ iwájú. [1]

Lẹ́yìn ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí MVA, àwọn àmì kan wà tí ó yẹ kí obìnrin fọkànsí kí ó sì lọ sí ilé ìwòsàn kí àwọn nǹkan wọ̀nyí má baà ṣẹlẹ̀ [2]:

  • Sísun ẹ̀jẹ̀ gidigidi (rírẹ àwọtẹ́lẹ̀ nǹkan oṣù méjì ní wákàtí kan fún wákàtí méjì léraléra tàbí ju bẹ́ẹ̀ lọ)
  • Ibà (ìgbóná gidigidi) tí ó ju wákàtí mẹ́rin lélógún lọ lẹ́yìn ètò ná
  • Ìnira eegun ìdí tí ó burú gidi
  • Àmì oyún yóò ma farahàn síwájú síi (èébì, ọmú rírọ̀ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ)

Fún àlàyé síi

Kàn sí àwọn olùdámọ̀ràn wá láti rí àlàyé síi lórí ìsẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí bí MVA àti EVA ìwọ yóò sì gba àtìlẹ́yìn lórí ọ̀nà ìsẹ́yún tí ó da fún ipò rẹ. O tún le mọ̀ síi nípa ọ̀nà kejì, ìsẹ́yún pẹ̀lú òògùn bí oyún rẹ kò bá tíì tó ọ̀sẹ̀ kọkànlá.

Àwọn ọ̀ǹkọ̀wé:

Ńipasẹ̀ ikọ̀ safe2choose àti àwọn ọ̀jọ̀gbọ́ ní carafem, ní ìbámu pẹ̀lú ìmòràn Ìgbìmò Àpapò lórí ètò Owó fún Ìṣẹ́yún ní ọdún 2020, ìmọ̀ràn àjọ Ipas ní ọdún 2019 àti ìmọ̀ràn WHO ní ọdún 2012

carafem ń pèsè ètò ìṣẹ́yún àti ìfètò sọ́mọ bíbí tí ó rọrùn tí ó sì dájú kí àwọn ènìyàn le ṣàkóso iye àti àyè tó wà láàárín àwọn ọmọ wọn

Ipas jẹ́ àgbárí òkèèré kan ṣoṣo tí ó gbájúmọ́ fífi ètò sí oyún ṣíṣẹ́ tí kò léwu àti ìbójútó èlà mágboyín

WHO jẹ́ abẹ̀wẹ̀ alámọ̀já ti Àjọ Àgbáyé tó wà lákoso ìlera àwùjọ ẹ̀dá káríayé

[1] World Health Organization (WHO). Safe abortion: technical and policy guidance for health systems, second edition. 2012. Récupéré de: https://apps.who.int/iris/bitstream/handle/10665/70914/9789241548434_eng.pdf;jsessionid=F77B761669FC579124C1E9CA2CC3CFDB?sequence=1

[2] Ipas. Clinical Updates in Reproductive Health. 2019. Récupéré de: https://www.ipas.org/wp-content/uploads/2023/09/Ipas-Clinical-Updates-in-Reproductive-Health-CURHE23b.pdf

Safe Abortion with Pills Options

Download resources

Check out the Manual Vacuum Aspiration video